Burna Boy yí ìpinnu padà, yóò kópa ní àjọ̀dún orin lórílẹ̀-èdè South Áfríkà

Aworan Burna Boy

Oríṣun àwòrán, Twitter/burnaboy

Àkọlé àwòrán, Burna Boy

Gbajugbaja olorin takasufe ọmọ Naijiria Burna Boy ti ni oun yoo jọwọ lara owo tawọn ba pa nibi ode orin ti yoo waye lorileede South Africa fawọn to farakasa Xenophobia.

Loju opo Twitter rẹ ni akọrin yii ti fi ọrọ naa hande.

Ṣaaju asiko yii, Burna Boy ti leri pe oun ko ni fẹsẹ tẹ ilẹ South Afrika nitori idẹyẹsi sawọn ọmọ ilẹ Afrika mIiran to n waye nibẹ.

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n

Ajọdun orin ti o fẹ kopa yii ni yoo jẹ igba akọkọ ti Burna Boy yoo tẹ South Afrika lati ọdun 2017.

Lara awọn ti wọn yoo jijọ fi orin bẹnu atẹ lu idẹyẹsi awọn eeyan ilẹ miran ní South Afrika la ti ri awọn akọrin bi Kwesta Jidenna ati Busiswa.

Akori ajọdun orin naa ti yoo waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla ni ''Afirika, pawọ pọ''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: