2020
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa Ìwé-ìtàn Ẹbí
Oṣù Kejì (Erele) 2020


Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejì (Erele) 2020

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa Ìwé-ìtàn Ẹbí

Àwòrán
ministering

Àpèjúwe látọwọ́ Joshua Dennis; àwòrán àtilẹ̀bá àti fọ́tò látinú àwọn àwòrán Getty

Ríran ẹnìkan lọ́wọ́ pẹ̀lú ìwe-ìtàn ẹbí jẹ́ ọ̀nà alágbára láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́. Bi ẹ ti nso àwọn ẹlòmíràn mọ́ àwọn bàbánlá wọn nípa àwọn ìtàn ẹbí àti ní kíníkíní, ẹ o pari pẹ̀lú kíkún àwọn àlàfo nínú ọkàn wọn nígbàmíràn tí wọ́n kò mọ̀ pé wọ́n ti ní rí (wo Málákì 4:5–6).

Bóyá ó jẹ́ ọmọ Ìjọ títí-ayé tàbí ẹnìkan tí kò gbọ́ nípa ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì rí, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ìtara láti mọ̀ nípa ibi tí wọ́n ti wá.

Kìí fìgbàkugba gba àkokò púpọ̀ láti fi ìtẹ̀mọ́rà pípẹ́-títí sílẹ̀, bí wọ́n ṣe júwe nínú àwọn ìtàn wọ̀nyí.

Wíwá Ẹbí ní ìṣísẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọgbọ̀n

Láìpẹ́ lórí fífò lọ sílé, mo rí arami lẹgbẹ Steve, ẹnití ó ṣe àbápín apákan ìtàn araẹni rẹ̀ pẹ̀lú mi. Ó ti ṣetán láti ilé-ìwé gíga, wọnú Ogun U.S. bí agboye ìbánisọ̀rọ̀ ní ọjọ́ orí méjìdínlógún, àti pé láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni Ilé Funfun, ní pípèsè àtìlẹhìn ìbánisọrọ̀ sí Ààrẹ United States. Láti ọjọ́ orí méjìdínlógún sí mẹ́rìndínlọ́gbọ́n, ó sin àwọn Ààrẹ U.S. méjì. Àwọn ìtàn rẹ̀ dùnmọ́ni!

“Steve,” mo wípé, “o níláti kọ àwọn ìtàn wọ̀nyí sílẹ̀ fún àwọn àtẹ̀lé rẹ! Wọ́n nílò láti ní àwọn ìtàn wọ̀nyí lọ́wọ́kan látinú ìgbìrò rẹ̀.” Ó faramọ.

Lẹ́hìnnáà Ẹ̀mí ṣí mi létí láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ohun tó mọ̀ nípa àwọn bàbánlá rẹ̀. Steve mọ ohun púpọ̀ nípa ẹ̀gbẹ́ ti ìyá rẹ̀, àti ìtàn kan bí ẹbí rẹ̀ ti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ nígbàkan rí pẹ̀lú Abraham Lincoln nígbàtí ó ti npolongo ní ẹ̀gbẹ́-orílẹ̀èdè nígbà ìbò ti ààrẹ U.S. ní 1860.

Ó mọ díẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti bàbá rẹ̀, bákannáà. Ó fẹ́ láti mọ̀ síi lódodo. Mo fa fóònù mi síta mo sì ṣí áàpù ÌwákiriẸbí. “Steve, a lè wá ẹbí rẹ báyìí!”

Mo sopọ̀ sí inú Wí-Fì. Mo fi fóònù mi sílẹ̀ sórí tíréè tábìlì ní iwájú mi kí àwà méjèèjì lè ri. A ṣe ìwákiri IgiẸbí. Ní àárín ìṣẹ́jú díẹ̀ àwà méjèèjì nwo ìwé-ẹ̀rí ìgbeyàwó bàbá-bàbá àgbà rẹ̀.

Ó wípé “Àwọn nìyẹn!”. “Mo rántí orúkọ rẹ tó kẹ́hìn báyìí!”

Ẹ̀mí inúdídùn dà le àwa méjèèjì lórí. A ṣiṣẹ́ lórí gbígbé àwọn prófáìlì fún àwọn bàbánlá tí a kò mọ̀-púpọ̀ fún ìṣẹ́jú marundinlaadọtà tó tẹ̀le. Ó ní kí nṣèlérí fún òun pé aó tẹ̀síwájú nínú ìwákiri papọ̀ ní Colorado. A ṣe arọ́pò ìwífúnni ìwánikàn bí ọkọ̀ òfúrufú ṣe balẹ̀.

Nihin la wà, ní fífò ẹsẹ̀ ọgbọ̀n ẹgbẹ̀run (mítà ẹgbẹ̀rún mẹsan ó lé àrúnlélógóje) ni òfúrufú, pẹ̀lú ohun-èlò kékeré bí ọwọ́ mi, wíwá ọkùnrin kan àti obìnrin kan tó ti ṣègbeyàwó lọ́gọ́ọ̀rún ọdún sẹ́hìn ẹnití ó ti sọnù si òun àti ẹbí rẹ̀. Ó yanilẹ́nu! Ṣùgbọ́n a rí wọn. Ẹbí sopọ̀. A rántí àwọn ìtàn. A ní ìmọ̀lára ìmoore fún àwọn ohun ìgbàlódé àti àwọn ohun èlò. Kò kéré jù ìṣẹ́ ìyanu lọ.

Jonathan Petty, Colorado, USA

Ẹbí Titun yí wọn ká

Màríà kìí wá déédé síjọ̀ fún ogún ọdún ó lé. Oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, a lo wákàtí díẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé wa, ní yíyẹ ìkani ẹbí rẹ̀ wò àti àwọn àkọsílẹ̀ míràn. Nígbà kan ó búsẹ́kún ó pariwo, “Mo ti kẹ́kọ púpọ̀ si nípa àwọn ẹbí mi ní wákàtí méjì ju bí mo ti mọ̀ ní gbogbo ayé mi!”

Ní òpin àkokò wa papọ̀, a fi àwọn Ìbátan Àyíká Mi tó yọ lórí Áàpù IgiẸbí hàn án. O hàn pé ọkọ mi àti èmi bá Màríà tan lọ́nà jíjìn. Ó bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kansi, ó wípé òun rò pè òun dá wà ni. Kò mọ̀ rárá pé òun ní ẹbí ní agbègbè náà. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìnnáà Màríà pàdé bíṣọ́ọ̀pù wa. Ó nṣiṣẹ́ báyìí lórí mímúrasílẹ̀ fún tẹ́mpìlì, àti pé ó ti pàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kọ́sìn “titun” ní wọ́ọ̀dù wa!

Carol Riner Everett, North Carolina, USA

Ìjúwe fún Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Ashley, arábìnrin kan tí mò nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí, àti èmi ní àwọn ìwé síse oúnjẹ látọ̀dọ̀ àwọn ìyá àgbà wa. Tirẹ̀ wa látọ̀dọ̀ ìyá-ìyá rẹ̀, àti pé tèmi ni ìwé kan tí mo gbé papọ̀ nígbàtí mo jogún àpótí ìjúwe ìyá-àgbà Greenwood lẹ́hìn tó kú.

Ashley àti èmi jìjọ yan ìjúwe látinú àwọn ìwé síse-oúnjẹ, a sì wá papọ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan lẹ́hìn iṣẹ́ láti gbìyànjú wọn. Ó yan ìjúwe dẹ́sàtì, nítorínáà a ṣeé lakọkọ a sì gbe sínú iná. Mo yan ṣípú dipù—ohun dídájú kan ní gbogbo ayẹyẹ ẹbí Greenwood. Ọmọbìnrin Ashley Alice rànwálọ́wọ́ láti tọ́ oúnjẹ wò. Lẹ́hìnnáà, nítorí Ashley kò fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ gbogbo dẹ́sátì, ó fi àwọn kan fún àwọn arábìnrin èyí tí òun nṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí.

Ohun tí mo fẹ́ràn jù nípa alẹ́ ìjúwe wa ni pé bí a ṣe nsè tí a sì nyan, a sọ̀rọ̀ nípa gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ déédé ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́—ìlàkàkà rẹ̀ àti ẹmi. Ṣùgbọ́n bákannáà a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyá-àgbà àti ìyá wa, èyí tí ó jẹ́ ìrọ́nú fún àwa méjèèjì.

Jenifer Greenwood, Utah, USA

Àwọn Kókó Ọ̀nà láti Ṣèrànlọ́wọ́

Ìwé-ìtàn ẹbí lè ṣí àwọn ilẹ̀kùn fún àwọn ànfàní fún ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nígbàtí ó dàbí kò sí ohun míràn. Nihin ni àwọn èrò díẹ̀ tí ẹ lè gbìyànjú.

  • Ẹ rànwọ́nlọ́wọ́ láti kọsìlẹ̀ àti láti gbé àwọn àkọsílẹ̀ gbígbọ́ sínú àwọn ìtàn ìwé-ìtàn ẹbí, nípàtàkì àwọn wọnnì tó bá fọ́tò mu.

  • Dá fáànù ṣáàtì kan tàbí òmíràn ìwé olùtẹ̀ ìwé-ìtàn ẹbí tí ẹ lè fúnni bí ẹ̀bùn kan sílẹ̀.

  • Kọ́ ní àwọn ọ̀nà láti gba ìwe-ìtàn ti ara wọn nípa pípa ìwé-ìròhìn mọ́ ní ọ̀ná tí wọ́n gbádùn. Gbígbọ́ ìwe-ìròhìn? Fọ́tò ìwé-ìròhìn? Àwọn lọ́ọ̀gì Fìdíò? Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíyàn wà fún àwọn wọnnì tí wọn kò fẹ́ ìlànà òdiwọn ìwé-ìròhìn-ẹni.

  • Ẹ lọ sí tẹ́mpìlì papọ̀ láti ṣe àwọn ìlànà fún àwọn bàbánlá. Tàbí gbà láti ṣe àwọn ìlànà fún àwọn orúkọ ẹbí wọn tí wọ́n bá ni ju iye tí wọ́n lè ṣe lọ.

  • Ẹ parapọ̀ láti ṣe àbápín àwọn àṣà ẹbí.

  • Gba kíláàsì ìwé-ìtàn ẹbí kan papọ̀.